Ìdí pàtàkì akọ́lé ẹ̀kọ́ yi ni "lati di àtúnbí ninu Omi ati Ẹ̀mí." Ó jẹ́ kókó pàtàkì ninu ẹ̀kọ́ yi. Ni èdè miran, iwe yi nsọ fun wa ní kedere ohun ti àtúnbí jẹ ati bi a ṣe le di àtúnbí nipa omi ati Ẹ̀mí ni ibamu ti o múná dóko gẹgẹ bi Bibeli ti wi. Omi yi túmọ̀nsí ìrìbọmi tí Jesu ṣe ninu odò Jordani, Bibeli si wipe gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa ni a ti rékọjá sori Jesu nigbati Ó ṣe ìrìbọmi ni ọ̀dọ̀ Johannu onítẹ̀bọmi. Johannu jẹ aṣojú gbogbo eniyan ati ọmọ-ọmọ Aaroni olórí alufa. Aaroni gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹran ètùtù na o si ré gbogbo ẹṣẹ awọn ọmọ Israeli ti ọdún kan kọjá si orí rẹ̀ ni ọjọ́ ètutu nla. Eyi jẹ òjìjí ohun rere ti mbọ wa. Ìrìbọmi Jesu ni apẹẹrẹ ìgbọ́wọ́lé. Jesu ti ṣe ìrìbọmi ni ọ̀nà ìgbọ́wọ́lé ninu odò Jordani. Nitorinaa Ó kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aiye yi lọ nipasẹ ìrìbọmi Rẹ o si kan-an mọ́ àgbélèbú lati san gbésé ẹṣẹ wa. Ṣugbọn ọpọlọpọ Kristiani ni kò mọ idi ti Johannu onítẹ̀bọmi fi ṣe ìrìbọmi fun Jesu ninu odò Jordani. Ìrìbọmi Jesu ni kókó ọ̀rọ̀ ti mbẹ ninu iwe yi, ti o si jẹ ohun pataki fun Ìhìnrere ti Omi ati ti Ẹ̀mí. A lè di àtúnbí nipa igbagbọ ninu ìrìbọmi Jesu ati àgbélèbú Rẹ nikan.